HYMN 365

(FE 387)
Golden Bells. No 432 S.S & S 599
“Oke giga kart hau" - I l l . 21:10



1.  ILE ayo kan wa l’oke 

     Ti o ndan ti o si l‘ewa

     Ayo ibe ki si d’opin 

     L’osan tabi l’oru 

     Awon Angeli nkorin 

     Y‘ite Mimo na ka 

     Nigbawo lao ri O

     lle to dara julo. 

Egbe:  A! ile didan, 

           A! ile didan

           Ile Olugbala, 

           ile to l’ogo julo.


2.  Kerubu ati Serafu

     E je k’a yin Oluwa 

     Fun idasi wa lojo oni 

     Iyin fun Metalokan 

     Se ranti p’Oluwa mbo 

     Lati ko wa lo sile 

     Nigbawo lao ri O

     Ile t'o dara julo.

Egbe:  A! ile didan...


3.  Kikankikan l’Oluwa npe 

     Eda ko si mira

     Ikore si nfe ka

     E je k’a sa fun ese

     Ki Jesu le we wa mo 

     Ye fun ‘le nla l'oke 

     Nigbawo lao ri O 

     Ile t‘o dara julo.

Egbe:  A! ile didan...


4.  Awon to ti jagun koja

     Nwon nwo wa bi a ti nja 

     Nwon mha O agutan k‘egbe 

     Oba lo si je fun won

     lbanuje ko si n‘ibe 

     Ninu ile didan na

     Nigbawo lao ri O 

     Ile to dara julo.

Egbe:  A! ile didan...


5.  lwo ki yio jijakudi 

     K‘o ba Olugbala joba 

     Nibi Kerubu Serafu 

     Yi ite Olugbala ka 

     lbugbe Olugbala 

     T‘ao ma sin titi 

     Nigbawo lao ri O

     Ile to dara julo.

Egbe:  A! ile didan...


6.  Nigbat'o ba d'ojo kehin 

     Ti a o si de 'joba Re 

     K’a gbo ohun ayo yi pe 

     Bo s'ayo Oluwa re 

     Kerubu, Serafu, yo 

     E gb‘ade iye nyin 

     Nigbana lao ri O

     Ile to dara julo.

Egbe:  A! ile didan, 

           A! ile didan

           Ile Olugbala, 

           ile to l’ogo julo.  Amin

English »

Update Hymn