HYMN 364

(FE 386) C.M.S 414 S.M H.C 410 
S.M
"Awon eni, nipa igbagbo ati suru 
ti o jogun ilerli wonni" - Heb. 6:12



1.  F’AWON enia Re,

     T'o ti fi aiye sile

     Awon to mo O, t’ o sin O, 

     Gba orin iyin wa.


2.  F’awon enia Re

     Gba ohun ope wa

     Awon t’o fi O s’esan won 

     Nwon ku n‘gbagbo Re!


3.  Ni gbogbo aiye won 

     ‘Won ni nwon nwo l'oju 

     Emi Mimo Re l’onko won 

     Lati s‘ohun gbogbo.


4.  Fun eyi, Oluwa,

     A nyin oruko Re

     Je k‘a ma tele iwa won

     Ki a le ku bi won.  Amin

English »

Update Hymn