HYMN 359

1.  Ejuba Olorun, wa, Jah 

     Oba onife julo 

     Olubori, Ajabori,

     Oba Orun on Aiye, 

Egbe:  Ijinle loro na, 

           Awamaridi si ni.


2.  Bayi l’o dawon eda Re 

     B’o ti wu O l’o da won 

     Awimayehun sa ni O 

     Awamaridi ni O.

Egbe:  Ijinle loro na...


3.  Nibit'ona ko ti si ri 

     Nibe ni ‘joko mi wa 

     Nip'agbara at’asa mi 

     Larin awon enia mi. 

Egbe:  Ijinle loro na...


4.  A ha ri eni le pada

     Gba mba nsise ogo mi 

     Awon Angel’ to l‘agbara 

     Nwon ko je dan eyi wo. 

Egbe:  Ijinle loro na...


5.  Lusifa t‘o l’agbara ju 

     Gbogbo awon Angel‘ lo 

     O f’owo pa ‘da mi loju 

     O si d’eni ifibu.

Egbe:  Ijinle loro na...


6.  Egbegberun ogun orun 

     L’o nso ti agbara mi, 

     Ogo, Ola ati ‘pa mi 

     Nwon njuba Agbara mi. 

Egbe:  Ijinle loro na...


7.  Sibe Emi ko yan eyi

     T’o ga julo ninu won 

     Sugbon Maikel t‘o kereju 

     Ni mo gbega ninu won. 

Egbe:  Ijinle loro na...


8.  Agbara ninu Agbara 

     Ogo, Ola at’ipa 

     Teru, teru, tifetife, 

     lfe si l’oruko mi.

Egbe:  Ijinle loro na, 

           Awamaridi si ni.  Amin

English »

Update Hymn