HYMN 358

(FE 381) s.d.m.r.d.s.l.l d.t.d.l.s: 
"OIorun wipe ki imole ki o wa" 
- Gen. 1:3



1.  BABA to da orun meje 

     Ati ‘le meje pelu

     Aiye lo se ekedogun 

     lyin ni f’oruko Re. 

Egbe:  Ijinle loro na 

           Awamaridi si ni, 

           Ijinle loro na 

           Awamaridi si ni.


2.  Orun, Osupa, Irawo 

     Awon ni ‘mole aiye 

     Okuta Oniyebiye 

    Awon ni ‘mole ‘sale. 

Egbe:  Ijinle loro na...


3.  Abo Oluwa Onike 

     L’awa Egbe bora mo

     Ko s‘ohun ‘bi to le se wa 

     Lagbara Metalokan.

Egbe:  Ijinle loro na...


4.  Eni loyun a bimo la 

     Agan a t’owo b‘osun 

     Olomo ko ni padanu 

     Iku ko ri wa gbe se.

Egbe:  Ijinle loro na...


5.  Ko s’eniti nri ‘di okun 

     A ki nri ‘di olosa

     Baba to da orun on aiye

     Ma je k’aiye r’idi mi.

Egbe:  Ijinle loro na...


6.  Awon Agbara Emi meje

     Ta fi wo HOLY MICHAEL 

     To si fi segun Lusifa

     Lojo ogun Olorun.

Egbe:  Ijinle loro na...


7.  Baba, Omo, Emi Mimo 

     Metalokan to gunwa 

     Jowo ko gbo adura wa, 

     Larin Egbe Serafu.

Egbe:  Ijinle loro na 

           Awamaridi si ni, 

           Ijinle loro na 

           Awamaridi si ni.  Amin

English »

Update Hymn