HYMN 357

(FE 380) C.M.S 259 H.C 247 D.S.M
“Be Ii awa o si wa Iai lodo Oluwa" 
- 1 Thess. 4:17



1.  ‘LAI lodo Oluwa! 

     Amin, beni ko ri 

     Iye wa ninu oro na 

     Aiku ni titi lai 

     Nihin ninu ara

     Mo sako jina si 

     Sibe, alale ni mo nfi 

     Ojo kan sunmole.


2.  Ile Baba loke

     Ile okan mi ni

     Emi nfi oju igbagbo 

     Wo ‘bode wura re! 

     Okan mi nfa pupo 

     S'ile na ti mo fe

      Ile didan t'awon mimo 

     Jerusalem t’orun.


3.  Awosanma dide 

     Gbogbo ero mi pin

     Bi adaba Noa, mo nfo, 

     Larin iji lile

     Sugbon sanma kuro

     lji si rekoja

     Ayo ati alafia

     Si gba okan mi kan.


4.  Loro ati l’ale

     Losan ati l'oru

     Mo ngbo orin orun, bori 

     Rudurudu aiye

     Oro ajinde ni

     Hiho isegun ni 

     Lekan si “Lai lod’Oluwa” 

     Amin, beni k’o ri.  Amin

English »

Update Hymn