HYMN 352

(FE 375) C.M.S 249 H.C 24, 11s 
“Eniti o ba segun ni yio jogun 
nkan wonyi” - Ifi. 21:7



1.  ILE ewa wonni, b’o ti dara to 

     Ibugbe Olorun, t’oju ko ti ri

     Tal’ o fe de ibe, lehin aiye yi? 

     Tal’o fe k‘a wo on ni aso funfun.


2.  Awon wonni ni, t’oji nin’ orun won

     Awon t‘o ni gbagbo si nkan t'a ko ri 

     Awon t‘o k’aniyan won l’Olugbala 

     Awon ti ko tiju agbelebu Krist.


3.  Awon ti ko nani gbogbo nkan aiye 

     Awonm t’o le soto de oju iku 

     Awon t’o nrubo ife L’ojojumo 

     Awon ta f ’igbala Jesu ra pada.


4.  ltiju ni fun nyin, om'ogun Jesu 

     Enyin ara ilu ibugbe orun 

     Kinla! e nfi fere at’ilu sire

     'Gbat’ o ni k’e sise t'o si pe, E ja!


5.  B'igbi omi aiye si ti nkolu wa 

     Jesu Oba ogo, so si wa leti

     Adun t'o wa l'orun, ilu mimo ni, 

     Nibit’ isimi wa lai ati lailai.  Amin

English »

Update Hymn