HYMN 35

C.M.S. 29 o.t. H.C 17, L.M  (FE 52) 
“Omo Enia li Oluwa ojo isinmi"
- Matt 12:8


1.  OLUWA ojo isimi,

     Gbo tiwa, pelu wa loni 

     Awa pade fun adura

     A fe gb’oro T’o fi fun wa.


2.  Isimi t’aiye yi rorun 

     Sugbon isimi t’orun dun 

     Lala okan wa fe ‘jo na 

     T'a o simi lailese da.


3.  Ko s’ija, ko si ‘dagiri

     Ko s’aniyan bi t’aiye yi 

     T‘y’o dapo mo ikorin wa, 

     T’o nt’ete aiku jade wa.


4.  Bebe, ojo t’a ti nreti 

     Afemoju re l’a fe ri

     A fe yo Iona ise yi,

     K’a sun n’iku, k’a ji l’ayo.  Amin

English »

Update Hymn