HYMN 346

(FE 369)
"E gbe orin nyin soke" - Ps. 24:9



1.  E GB'ori nyin soke enu ona, 

     K’Oluwa ogo wole

     Enit’ O f‘eje re r’aiye pada 

     O mbo lati gba ‘joba. 

Egbe:  Hosannah, enyin Orun

           Halleluyah, eyin Aiye,

           Orun, Osupa, e wole 

           Kabiyesi, f 'Oba wa.


2.  Awa Iran Israeli ni Afrika 

     E gb‘ola Oluwa ga

     Ajagun -molu Wa ti goke lo 

    Lati lo pese aye. 

Egbe:  Hosannah, enyin Orun...


3.  Wo, Oba wa ninu Olanla Re, 

     Gun keke Ofurufu

     Agogo Orun pelu korin lyin 

    ‘Ghat’Oba Ogo wole. 

Egbe:  Hosannah, enyin Orun...


4.  Okan mi nfa s‘Agbala ayo na 

     Nibiti Kristi gunwa

     Odi yika ati Agbala Re

     Wura l'a fi se loso. 

Egbe:  Hosannah, enyin Orun...


5.  Agbara Merinlelogun wole

     Pelu ade wura won

     At'awon Eda Alaye merin

    Nwon nfi iye fo f 'ayo. 

Egbe:  Hosannah, enyin Orun

           Halleluyah, eyin Aiye,

           Orun, Osupa, e wole 

           Kabiyesi, f 'Oba wa.  Amin

English »

Update Hymn