HYMN 345

(FE 368)
t.H.C 204 6s. 8s
"E ho iho ayo si Oluwa, enyin ile
gbogbo" - Ps. 100:1



1.  OLORUN goke lo 

     Pelu ariwo nla 

     Awon ipe orun

     Nfi ayo Angeli han.

Egbe:  Gbogbo aiye yo, k'e gberin

            E f'ogo fun Oba Ogo.


2.  O j’enia laiye 

     Oba wa ni loke 

     Ki gbogbo ile mo 

     lfe nla Jesu wa.

Egbe:  Gbogbo aiye yo...


3.  Baba fi agbara, 

     Fun Jesu Oluwa 

     Ogun Angeli mbo O 

     On l'Oba nla Orun.

Egbe:  Gbogbo aiye yo...


4.  L'or’ite re mimo 

     O gb‘opa ododo 

     Gbogbo ota Re ni 

     Yio ka lo bere.

Egbe:  Gbogbo aiye yo...


5.  Ola Re l’ota wa 

     Esu, aiye, ese

     Sugbon y'o r‘ehin won 

     ljoba Re y'o de.

Egbe:  Gbogbo aiye yo, k'e gberin

            E f'ogo fun Oba Ogo.  Amin

English »

Update Hymn