HYMN 342

(FE 365) 
H.C 232 t.Apa II D. 8s 7s
"owo otun Re, ati apap Re mimo, Ii o ti 
mu igbala wa fun ara re" - Ps. 96:1



1.  WO Asegun b’o ti goke 

     Wo Oba n'nu ola Re 

     Ogun keke ofurufu

     Lo s' orun agbala Re 

     Gbo orin awon Angeli 

     Halleluya ni nwon nko 

     Awon 'lekun si si sile 

     Lati gba Oba Orun.


2.  Tani Ologo ti mbo yi 

     T'on ti ipe jubeli 

     Oluwa awon ‘mo-ogun 

     On to ti segun fun wa 

     O jiya lor'agbeleu 

     O jinde ninu oku

     O segun Esu at’ese 

     Ati gbogbo ota Re.


3.  B'o ti nbuk‘awon ore Re 

     A gba kuro lowo won

     Bi oju nwon si ti nwo lo 

     O nu nin’ awosanmo 

     Enit' o ba Olorun rin 

     T’o si nwasu otito 

     On, Enoku wa, l’a gbe lo 

     S‘ile Re loke orun.


4.  On, Aaron wa, gbe eje Re, 

     Wo inu ikele lo

     Josua wa, ti wo Kenaan 

     Awon oba nwariri

     A fi 'di eya Israel 

     Mule nibi ‘simi won 

     Elija wa si fe fun wa 

     N'ilopo meji Emi.


5.  lwo ti gbe ara wa wo

     Lo s'ow' otun Olorun

     A si joko nibi giga

     Pelu Re ninu ogo

     Awon Angeli mbo Jesu 

     Enia Joko Ior'ite

     Oluwa, b‘lwo ti goke 

     Jo je k'a le goke be.  Amin

English »

Update Hymn