HYMN 338

C.M.S 237 D.7s (FE 361)
“Ago re wonni ti I‘ewa to"
- Ps. 84:1



1.  ‘BUGBE Re ti l’ewa to! 

     Ni le ‘mole at'ife 

     ‘Bugbe Re ti l'ewa to! 

     Laiye ese at’osi

     Okan mi nfa nitoto 

     Fun idapo enia re 

     Fun imole oju Re 

     Fun ekun Re, Olorun.


2.  Ayo ba awon eiye

    Ti nfo yi pepe Re ka 

    Ayo okan l'o simi 

    L'aiya Baba l'o poju

    Gege b'adaba Noa

    Ti ko r’ibi simi le 

    Nwon pada sodo Baba 

    Nwon si nyo tili aiye.


3.  Nwon ko simi iyin won 

     Ninu aiye osi yi

     Omi nsun ni aginju

     Manna nt‘orun wa fun won 

     Nwon nlo Iat‘ ipa de ‘pa 

     Titi nwon fi yo si O

     Nwo si wole l'ese Re 

     T'O mu won la ewu ja.


4.  Baba, je ki njere be 

     S'amona mi l'aiye yi 

     Fore ofe pa mi mo 

     Fun mi l'aye lodo Re 

     lwo l'orun at'Asa

     To okan isina mi 

     lwo l‘orisun ore 

     Ro ojo re sori mi.  Amin

English »

Update Hymn