HYMN 337

P.B 167 11s (FE 360)
“Isimi kan ku fun awon enia Olorun"
- Heb. 4:9



1.  KINI ‘Simi ayo ailopin ni

     T'awon Angeli at‘awon mimo ni? 

     Simi f‘alare, f’awon asegun

     Nibe I‘Olorun je ohun gbogbo.


2.  Tal' Oba na? tani yi ‘te re ka 

     Irora itura Re na ti’ri?

     So funni, enyin ti njosin nibe 

     So funni, b' oro to t’ayo nyin so.


3.  Jerusalem toto, ilu mimo 

     Alafia eyi t‘o je kik’ayo

     A r'ohun t’a nfe n'nu re k’a to wi 

     A si ri gba ju eyi t’a nfe lo.


4.  L’agbala Oba wa, wahala tan 

     Laiberu l’ao ma korin Sion

     Oluwa, niwaju Re l'a o ma fi 

     Idahun ‘fe han f 'ebun ife Re.


5.  Simi ko le tele ‘simi nibe 

     Enikan ni ‘simi ti nwoju Re

     Nibe orin jubeli ko le tan 

     T'awon mimo at’angeli y’o ko.


6.  Laiye yi, pelu ‘gbagbo at’adua 

     L'a o ma safer ‘le Baba ohun

     Si Salem l'awon ti a si nipo 

     Npada lo; lat’ ilu Babiloni.


7.  Nje awa teriba niwaju Re 

     T’Eniti ohun gbogbo jasi

    Ninu eniti Baba at’Omo 

    T’eniti Emi je Okansoso lai.  Amin

English »

Update Hymn