HYMN 332

(FE 335) C.M.S 233 t.S.634 C.M
“Eyara lo so fun awon omo ehin Re
pa O jinde" - Matt. 28:7



1.  MO wi fun olukaluku 

     Pe, On ji, O si ye

     O si wa larin wa pelu 

     Nipa Emi iye.


2.  E wi fun enikeji nyin 

     Ki nwon ji pelu wa 

     K’imole k’o wa kakiri 

     Ni gbogbo aiye wa.


3.  Nisisiyi aiye yi ri

     Bi ile Baba wa

     lye titun ti On fun ni 

     O so d‘ile Baba.


4.  Ona okun ti On ti rin 

     Mu ni lo si orun

     Enit’ o rin bi On ti rin 

     Y'o d'odo Re l'orun.


5.  On ye, O si wa pelu wa 

     Ni gbogbo aiye yi

     Ati nigbati a f’ara wa, 

     F’erupe ni ‘reti.  Amin

English »

Update Hymn