HYMN 322

(FE 345)
C.M.S 222 t.H.C 383 6s 8s
“Nigbati nwon wo inu iboji, won
ko si ba oku Jesu Oluwa" - Luku 24:3



1.  OLUWA ji loto 

     Olugbala dide

     O f‘agbara Re han 

     L'or‘orun apadi

     N'iberu nla, awon eso 

     Subu lule, nwon si daku.


2.  Wo, egbe angeli

     Pade l'ajo kikun

     Lati gbo ase Re

     Ati lati juba

     Nwon f‘ayo wa, nwon si nfo lo 

     Lati orun si ‘boji na.


3.  Nwon tun fo lo s‘orun

     Nwon mu ‘hin ayo lo 

     Gbo iro orin won 

     Bi nwon si ti nfo lo 

     Orin won ni, Jesu t'o ku 

     Ti ji dide, o Ji Ioni.


4.  Enyin t‘a ra pada

     E gberin ayo na

     Run iro re kiri 

     Si gbogbo agbaiye

     E ho f'ayo, Jesu t‘o ku 

     Ti ji dide, ki y‘o ku mo.


5.  Kabiyesi! Jesu!

     T‘o Feje Re gba wa

     Ki iyin Re jale

     lwo t’o ji dide

     A ba O ji, a si joba

     Pelu Re lai, l'oke orun.  Amin

English »

Update Hymn