HYMN 321

t.H.C 97 7s (FE 344) 
“E lo so fun nawon omo ehin
Re pe O jinde” - Matt. 28:7



1.  Lo so fun gbogbo aiye 

     Lo tan ihin ayo yi

     Eti t'o ba gbo, y’o si, 

     Okan t’o ba gbo, y’o la.


2.  Jesu Olugbala wa, 

     T‘a sin, fi ‘boji sile 

     Olorun gba ebo Re,

     Ebo ese araiye.


3.  O ji lati ma ku mo 

     Akobi awon t‘o sun

    Eniti o ba gba a gbo

    Yio ye, b'o tile ku.


4.  Angeli! eda orun 

    E ba araiye gberin 

    Jesu OIudande ji, 

    Alafia titi lai.  Amin

English »

Update Hymn