HYMN 320

C.M.S 219 H.C 7s. 8s 4 (FE 343)
“Kiyesi i, emi mbe laye titi lai"
 - 1 Ifi. 1:18



1.  JESU ye, titi aiye 

     Eru iku ko ba ni mo 

     Jesu ye: nitorina

     Isa oku ko n'ipa mo 

     Alleluya.


2.  Jesu ye, lat‘ oni lo

     Iku je ona si iye

     Eyi y'o je ‘tunu wa 

     ‘Gbat‘ akoko iku ba de 

     Alleluya.


3.  Jesu ye, fun wa l’O ku 

     Nje Tire ni a o ma se 

     A o f'okan funfun sin 

     A o f'ogo f‘Olugbala 

     Alleluya.


4.  Jesu ye, eyi daju 

     lku at'ipa okunkun 

     Ki y‘o le ya ni kuro 

     Ninu ife nla ti jesu 

     Alleluya.


5.  Jesu ye, gbogbo 'joba 

     L‘orun, li aiye di Tire 

     E je ki a ma tele

     Ki a le joba pelu Re 

     Alleluya.  Amin

English »

Update Hymn