HYMN 32

C.M.S 34, H.C 220, C.M (FE 49) 
"Eyi ni ojo ti Oluwa da" - Ps. 118:24


1.  EYI I'ojo t'Oluwa da,

     O pe ‘gba na ntire

     K'orun k‘o yo, k‘aiye ko yo 

     K’iyin yi 'te na ka.


2.  Loni, o jinde ‘nu oku

     ljoba Satan tu

     ‘Won mimo tan ‘segun Re ka, 

     Nwon nsoro ‘yanu Re.


3.  Hosanna si Oba t‘a yan

     S‘Omo Mimo Dafidi 

     Oluwa, jo sokale wa, 

     T’ lwo t‘igbala Re.


4.  Abukun l‘Oluwa t'o wa 

     N'ise ore-ofe

     T'o wa l‘Oruko Baba Re, 

     Lati gba ‘ran wa la.


5.  Hosanna li ohun goro, 

     L’orin ljo t’aiye

     Orin t'oke orun lohun 

     Yio dun ju be lo.  Amin

English »

Update Hymn