HYMN 317

(FE 340)
ORIN AjKINDE JESU
"E ma ko Orile ede gbogbo" - Matt. 28:19



1.  LO kede ayo na fun 

     gbogho aiye

     P‘Omo Olorun segun iku

     Fi iyin-tiyin pel’ayo rohin na, 

     Emi Mimo to gunwa.

Egbe:  Oba mi de!

            Asegun mi de! 

           Ogo, Ola at'agbara ati 'pa 

           F 'Odagutan to gunwa.


2.  lyin Jesu l’awon

     Ange li nke

     T'o wa ra 'raiye pada

     Okan soso ajanaku ni Jesu, 

     T'o m'aiye pelu orun.

Egbe:  Oba mi de!...


3.  Kabiyesi Oba Alaiyeluwa 

     Metalokan Alagbara

     Awamaridi Olodumare

     T’o nse ise iyanu.

Egbe:  Oba mi de!...


4.  ltiju nla d a bo awon ika 

     T‘o kan Oluwa wa mo 'gi 

     Rikisi ikoko ota ti d' asan 

     Olugbala ji dide. 

Egbe:  Oba mi de!...


5.  Bi orile-ede enia dudu

     Ati ka wa si eweko

     Sugbon awa ni Baba kan l’oke 

     T’o mo pe ‘se Re ni wa.

Egbe:  Oba mi de!...


6.  Ayo t’o wa ninu Ajinde 

     Jowo fun wa Olugbala 

     ’Gbat’a ba yo si O Eleda wa 

     K’awa le gb’ade ogo.

Egbe:  Oba mi de!...


7.  Awa f‘ogo fun Baba wa l‘oke 

     A tun f'ogo fun Omo Re

     Awa tun f’ogo fun O Emi Mimo

     Metalokan l‘ope ye.

Egbe:  Oba mi de!

            Asegun mi de! 

           Ogo, Ola at'agbara ati 'pa 

           F 'Odagutan to gunwa.  Amin

English »

Update Hymn