HYMN 308

(FE 329)
"Nitori ore-ofe ni a ngba nyin la"
- Efe. 2:8 



1.  EKUN ko le gba mi,

     Bi mo le f'ekun we 'ju;

     Ko le mu eru mi tan,

     Ko le we ese mi nu;

     Ekin ko le gba mi.

Egbe:  Jesu sun, O ku fun mi,

            O jiya lori igi

            Lati so mi d'ominira

            On na l'O le gba mi.


2.  lse ko le gba mi

     lse mi t‘o dara ju

     Ero mi t'o mo julo

     Ko le s'okan mi d'otun 

     Ise ko le gba mi.

Egbe:  Jesu sun, O ku fun mi...


3.  ‘Duro ko le gba mi 

      Enit‘o junu ni mi

      L‘eti mi l’anu nke pe

      Bi mo ba duro ngo ku 

      ‘Duro ko le gba mi.

Egbe:  Jesu sun, O ku fun mi...


4.  Igbagbo le gba mi 

     Jeki ngbekel'Omo Re 

     Jeki ngbekele s’ise Re

     Jeki nsa si apa Re

     Igbagbo le gba mi.

Egbe:  Jesu sun, O ku fun mi,

            O jiya lori igi

            Lati so mi d'ominira

            On na l'O le gba mi.  Amin

English »

Update Hymn