HYMN 307

ORO MEJE KRISTI LORI AGBELEBU

H.C. 200 7s. 6.  (FE 328)
"Baba dariji won; nitori t nwon ko mo
ohun ti nwon se." - Luku 23:34



1.  IWO to bebe f'ota Re,

     L'or'igi agbelebu: 

     Wipe, “fiji won Baba,"

     Jesu, sanu fun wa.


2.  Jesu, jo bebe fun wa, 

     Fun ese wa ‘gbagbogbo; 

     A ko mo ohun t’n se, 

     Jesu, sanu fun wa.


3.  Jek’ awa ti nwa anu, 

     Dabi Re l ‘kan n’ iwa, 

     ‘Gbat’aba se wa n’ibi: 

     Jesu, sanu fun wa.


“Loni ni iwo o wa pelu mi ni 
paradise." - Luku 23:43


4.  Jesu, ‘Wo t’o gbo aro, 

     Ole t’ oku l’ egbe Re, 

     T’ o si mu d’ orun rere: 

     Jesu, sanu fun wa.


5.  Ninu ebi ese wa,

     Jek’ a toro anu Re,’ 

     K' a ma pe oruko Re: 

     Jesu, sanu fun wa.


6.  Ranti awa ti nrahun, 

     T‘ a nwo agbelebu Re; 

     F’ ireti mimo fun wa, 

     Jesu, sanu fun wa.

"Obinrin, wo Omo re, wo iya re."
- John. 19:26, 27


7.  Wo t'o fe l'afe dopin 

     Iya  Re t'o n kanu Re,

     Ati ore Re owon:

     Jesu saanu fun wa.


8.  Jek'apin n'nu iya Re,

     K' a ma ko iku fun O,

     Jek’ a ri ‘toju Re gba: 

     Jesu, sanu fun wa.    


9.  Ki gbogbo awa Tire,

     Je omo ile kanna;

     Tori Re, k’a fe ‘ra wa:

     Jesu, sanu fun wa.


“Olorun mi, Olorun mi, ese ti iwo 
fi ko mi sile.” - Matt. 27:46

10.  Jesu, ‘Wo ti eru mba, 

       ‘Gbat’ o si ku Wo nikan, 

       Ti okunkun su bo O: 

       Jesu, sanu fun wa.


11.  ‘Gbati a ba npe lasan, 
 
       T’ ireti wa si jina; 

       N’nu okun na di wa mu;

       Jesu, sanu fun wa.


12.  B’od dabi Baba kogbo, 
   
       B’ o dabi ‘moleko si,

       Jek’ a f' igbagbo ri O, 

       Jesu, sanu fun wa.


“Orungbe ngbe mi." ‐ John 19:30B


13.  Jesu, ninu ongbe Re, 

       Ni ori agbelebu, 

       ‘Wo ti o fe wa sibe; 

       Jesu, sanu fun wa.


14.  Ma kongbe fun wa sibe, 

       Sise mimol’ ara wa;

       Te ife re na l’orun; 

        Jesu, sanu fun wa.


15.  Jek’ a kongbe ife Re, 

       Ma samona wa titi, 

       Si'bi omi iye ni: 

       Jesu, sanu fun wa.


“O pari." - John. 19:30


16.  Jesu Olurapada,

       ‘Wo t’ o se ‘fe Baba Re, 

       T' o si jiya’tori wa; 

       Jesu, sanu fun wa.


17.  Gba wa I'ojo idamu, 

       Se oluranlowo wa, 

       Lati ma t’ona mimo: 

       Jesu, sanu fun wa.


18.  F’ imole Re s’ ona wa, 

       Ti y’o ma tan titi lai, 

       Tit'ao fi de odo Re: 

       Jesu, sanu fun wa.  etc.


"Baba Ii owe Re ni mo fi emi mi 
le" - Luku 23:46


19.  Jesu, gbogbo ise re, 

       Gbogbo idamu Re pin; 

       O jow’ emi Re lowo: 

       Jesu, sanu fun wa.


20.  ‘Gbat’ iku ba de ba wa: 

       Gba wa lowo ota wa; 

       Yo wa wakati na: 

       Jesu, sanu fun wa.


21.  Ki iku at’ iye Re,

       Mu Oore-ore ba wa,

       Ti yio mu wa d‘oke: 

       Jesu, sanu fun wa.  Amin

English »

Update Hymn