HYMN 305

C.M.S 198. t.H.c. 190 C.M.
“Eje Kristi iyebiye" - 1Pet. 1:19



1.  OGO ni fun Jesu, 

     T’o f' irora nla, 

     Ta eje Re fun mi, 

     Lati iha Re.


2.  Mo r‘ iye ailopin, 

     Ninu eje na; 

     lyonu Re sa po, 

     Ore Re ki tan.


3.  Ope ni titi lai, 

     F'eje ‘yebiye,

     ‘T o ra aiye pada, 

     Kuro n’nu egbe.


4.  Eje Abel' nkigbe, 

     Si orun f' esan; 

     Sugb’ eje Jesu nke, 

     Fun ‘dariji wa.


5.  Nigbati a bu won, 

     Okan ese wa, 

     Satan, n' idamu re, 

     F'eru sa jade.


6.  Nigbat’ aiye ba nyo, 

     T’ongbe ‘Yin Re ga, 

     Awon ogun Angel, 

     A ma f' ayo gbe.


7.  Nje, e gbohun nyin ga, 

     Ki iro na dun!

     Kikan lohun goro,

     Yin Od' agutan.  Amin

English »

Update Hymn