HYMN 293

K. 154 t.H.C 94 S.M (FE 314)
"Eje Jesu Kristi Omo re ni nwe 
wa nu kuro ninu ese wa gbogbo"
 - 1 John 1:7



1.  GBOGBO eje eran,

     Ti pepe awon Ju

     Ko le f'okan l'alafia 

     Ko le we eri nu.


2.  Kristi Od'agutan 

     M‘ese wa gbogbo lo 

     Ebo t‘o ni oruko nla 

     T'o ju eje won lo.


3.  Mo f‘igbagbo gb‘owo 
   
     Le ori Re owon 

     B'enit’o ronupiwada 

     Mo jewo ese mi.


4.  Okan mi npada wo 

     Eru t'lwo ti ru

     Nigbati a kan O mo ‘gi 

     Ese re wa nibe.


5.  Awa nyoi ni ‘gbagbo 

     Bi egun ti kuro

     Awa nyin Odo-agutan, 

     A nkorin ife re.  Amin

English »

Update Hymn