HYMN 289

H.C 144. 7s (FE 310)
“Lati inu ibu wa Ii emi kepe O,
Oluwa" - Ps. 130:1



1.  ‘WO t’o ku ni Kalfari 

      Wo t’o mbebe f‘elese 

      Ran mi lowo, nigb’aini 

      Jesu, gbo ‘gbe mi.


2.  Ninu ibanuje mi, 

     At‘okan aigbagbo mi 

     Em'olori elese

     Gb’oju mi si O.


3.  Ota lode, eru n’nu 

     Ko s’ire kan lowo mi 

     Iwo t’o ngb’elese la 

     Mo sa to O wa.


4.  Awon miran dese pe 

     Nwon si ri igbala 

     Nwon gbo ohun anu Re 

     Mu mi gbo pelu.


5.  Mo k’aniyan mi le O 

     Mo si ngbadura si O, 

     Jesu, yo mi n'nu egbe 

     Gba mi, ki nma ku.


6.  ‘Gbati wahala ba de 

     Nigb’ agbara idanwo 

     Ati lojo ikehin

     Jesu, sunmo mi.  Amin

English »

Update Hymn