HYMN 288

C.M.S 196 H.C 460 C.M (FE 309)
"Hosannah fun Omo Dafidi" - Matt 21:9



1.  HOSANNA s'Omo Dafidi 

     Hosanna, e korin

     ‘Olubukun l’Eniti mbo 

     L'oruko Oluwa.


2.  Hosanna s’Omo Dafidi

     L’Egbe Angeli nke

     Gbogbo eda jumo gberin 

     Hosanna s'Oba wa.


3.  Hosanna! awon Heberu 

     Ja imo ope sona 

     Hosanna a mu ebun wa 

     Fi tun ona Re se.


4.  T'agba t’ewe nke Hosanna! 

     K‘ijiya Re to de;

     Loni, a si nko Hosanna! 

     B’O ti njoba l’oke.


5.  'B’O ti gba ‘yin won nigbana 

     Jo gba ebe wa yi

     Lorun ka le b’angel 'korin 

     Hosanna s'Oba wa.  Amin

English »

Update Hymn