HYMN 287

C.M.S 194 H.C 80 D.7s 6s. (FE 308)
"Hosanna fun Omo Dafidi" - Matt. 21:9



1.  GBOGB' ogo, iyin, ola 

     Fun O, Oludande 

     S'Eni t’awon omode

     Ko Hosanna didun! 

     ‘Wo! l‘Oba lsreali 

     Om'Alade Dafidi 

     T'o wa l‘Oko Oluwa 

     Oba Olubukun. 

Egbe:  Gbogb'ogo, iyin, ola 

            Fun O, Oludande,

            S'Eni t'awon omode 

            Ko Hosanna didun.


2.  Egbe awon Maleka 

     Nyin O Ioke giga 

     Awa at'eda gbogbo 

     Si dapo gberin na. 

Egbe:  Gbogb'ogo, iyin...


3.  Awon Hebru lo saju 

     Pelu imo ope

     lyin, adua at'orin 

     L‘a mu wa ‘waju Re.

Egbe:  Gbogb'ogo, iyin...


4.  Si O saju iya Re 

     Nwon korin iyin won 

     Wo t'a gbe ga nisisyi 

     L‘a nkorin iyin si. 

Egbe:  Gbogb'ogo, iyin...


5.  ‘Wo gba orin iyin won 

     Gb'adura t’a mu wa 

     Wo ti nyo s’ohun rere 

     Oba wa Olore.

Egbe:  Gbogb'ogo, iyin, ola 

            Fun O, Oludande,

            S'Eni t'awon omode 

            Ko Hosanna didun.  Amin

English »

Update Hymn