HYMN 276

H.C 2nD eD.,106 or
t.H.C 552 L.M (FE 296)
"On yio joba lati okun de okun
 - Ps. 72:8



1.  JESU yio joba ni gbogbo 

     lbit’a ba le ri orun 

     ‘Joba Re yo tan kakiri 

     ‘Joba Re ki y’o nipekun.


2.  On l’ ao ma gbadura si, 

     Awon oba yio pe l’Oba 

     Oruko Re b‘orun didun

     Y’o ba ebo oro goke.


3.  Gbogbo oniruru ede

     Y’o fi fe Re korin didun 

     Awon omode o jewo

     Pe, ‘bukun won t’odo Re wa.


4.  ‘Bukun po nibit’On joba 

     A tu awon onde sile 

     Awon alare ri isimi 

     Alaini si ri ‘bukun gba.


5.  O f'agbara iwosan han

     Iku, egun ko ni 'pa mo

     N'nu Re n'iran Adam nyangan

     'Won ri opo ibukun gba.


6.  Ki gbogho eda k'o dide

     Ki nwon f‘ola fun Oba wa;

     K’Angel‘ tun wa t‘awon t’orin

     Ki gbogb' aiye jumo gberin.  Amin

English »

Update Hymn