HYMN 267

C.M (FE 287)
"Oju Oluwa mbe nibi gbogbo"
 - Owe 15:3



1.  ISE gbogbo ti awa nse 

     Ni Olorun ti ri

     Ero gbogbo t'o wa ninu 

     Ni Olorun si mo.


2.  A ko le f‘ese wa pamo 

     Gbogbo won l'O ti mo 

     A npuro, a ntan ‘ra wa je 

     B’a ro pe ko mo won.


3.  Ohun gbogbo han ni gbangba 

     Ni oju Olorun

     Okunkun ati imole

     Si ri bakanna fun.


4.  Olorun, je k'a ranti pe 

     Oju re si ri wa

     Si jeki awa k’o beru 

     Lati dese si O.  Amin

English »

Update Hymn