HYMN 260

C.M.S.176 H.C 170 7s (FE 230)
"Nitori kini enyin o se ku, ile 
Israeli” - Ex. 33:11



1.  ELESE, e yipada

     Ese ti e o fi ku? 

     Eleda nyin lo mbere 

     T’o feki e ba On gbe 

     Oran nla ni o mbi nyin 

     lse owo Re ni nyin

     A! enyin alailope

     E se t’e o ko ‘fe Re.


2.  Elese, e yipada,

     Ese ti e o fi ku,

     Olugbala ni mbere 

     Enit’ o gb'emi nyin la; 

     Iku Re y’o j'asan bi?

     E o tun kan mo ‘gi bi? 

     Eni’rapada, ese

     Ti e o gan ore Re?


3.  Elese, e yipada

     Ese ti e o fi ku?

     Emi Mimo ni mbere

     Ti nf'ojo gbogbo ro nyin 

     E ki o ha gb'oro Re? 

     E o ko iye sile?

     A ti nwa nyin pe, ese 

     T’e mbi Olorun ninu?


4.  Iyemeji ha nse nyin 

     Pe ife ni Olorun? 

     E ki o ha gb'oro Re 

     K’e gba ileri Re gbo 

     W’Oluwa nyin, lodo nyin

     Jesu nsun, w'omije Re 

     Eje Re pelu nke, pe

     'Ese ti e o fi ku?  Amin

English »

Update Hymn