HYMN 258

C.M.S 173 H.C 163. D 7s 6s. (FE 278)
"Eni itewogba ninu Ayanfe" - Efe. 1:6s




1.  MO kese mi le, Jesu 

     Od'agutan Mimo

     O ru gbogbo eru mi 

     O so mi d' ominira 

     Mo ru ebi mi to wa 

     K’o we eri mi nu

     K'eje Re iyebiye 

     Le so mi di funfun.


2.  Mo k‘aini mi le Jesu 

     Tire l'ohun gbogbo 

     Ow‘arun mi gbogbo san 

     O  r'emi mi pada

     Mo ko ibanuje mi 

     Eru at'aniyan 

     Le Jesu, O si gba mi 

     O gba irora mi.


3.  Mo gb'okan mi le Jesu 

     Okan ara mi yi 

     Ow’otun Re gba mi mu 

     Mo simi laya Re

     Mo fe oruko Jesu 

     Emmanuel, Kristi. 

     Bi orun didun yika 

     Ni oruko Re je.


4.  Mo fe ki nri bi Jesu 

     Tokan Re kun fun ‘fe 

     Mo fe ki nri bi Jesu 

     Omo Mimo Baba

     Mo fe ki mba Jesu gbe 

     Larin egbe mimo

     Ki nkorin iyin titi

     Orin t‘Angeli nko.  Amin

English »

Update Hymn