HYMN 257

C.M.S 173 H.C 160 D 6s 5s (FE 277)
"Mo ti gbadura fun o, ki igbagbo 
re mase ye" - Luku 22:32



1.  JESU, nigba ‘danwo 

     Gbadura fun mi 

     K‘emi ma ba se O 

     Ki nsi sako lo

     Gba mba siyemeji 

     K'O bojuwo mi 

     K’eru tab‘isaju 

     Ma mu mi subu.


2.  B’aiye ba si nfa mi 

     Pelu adun re 

     T’Ohun ‘sura aiye 

     Fe han mi l’emo 

     Jo mu Getsemane 

     Wa s’iranti mi 

     Tabi irora Re, 

     loke Kalfari.


3.  B‘O ba pon mi loju 

     Ninu ife Re 

     Da ibukun Re Ie 

     Ori ebo na

     Ki nf'ara mi fun O 

     Lori pepe Re 

     B’ara ko ago na 

     Igbagbo y'o mu.


4.  ‘Gba mo ba nre ‘boji 

     Sinu ekuru

     T'ogo orun si nko 

     Leti bebe na

     Ngo gbekel’oto Re 

     N'ijakadi ‘ku 

     Oluwa, gb'emi mi 

     S‘iye ailopin.  Amin

English »

Update Hymn