HYMN 247

C.M.S 150 t.H.C 164
tabi H.C 140 C.M (FE 267) 
"Enyin pelu nfe lo bi?" - John 6:67



1.  NIGBA nwon kehin si Sion, 

     A! opo n'iye nwon

     Mo se b'Olugbala wipe

     Wo fe ko mi pelu?


2.  T’emi t’okan b'iru eyi

     A fi b'O di mi mu

     Nko le se ki nma fa s’ehin 

     K’emi si dabi won.


3.  Mo mo, lwo I’o l’agbara 

     Lati gba otosi

     Odo tani emi opo lo

     Bi mo kehin si O?


4.  O da mi loju papa pe 

     lwo ni Kristi na! 

     Enit' o ni emi iye 

     Nipa ti eje Re.


5.  Ohun Re f ’isimi fun mi 

     O si l‘eru mi lo

     lfe Re lo le mu mi yo 

     O si to f’okan mi.


6.  Bi ‘bere yi ti dun mi to

     ‘Pe emi o lo bi?

     Oluwa, ni ‘gbekele Re

     Mo dahun pe “Beko.”  Amin

English »

Update Hymn