HYMN 233

C.M.S 104 S.M (FE 253) 
"Ese won l’ori oke ti dara to” - Isa. 52:7



1.  ESE won ti da to 

     Ti nduro ni Sion

     Awon t‘o mu ‘hin gbala wa 

     Awon t‘o f’ayo han.


2.  Ohun won ti wo to 

     Ihin na ti dun to

     Sion, w'Olorun Oba re 

     B’o ti segun nihin.


3.  Eti wa ti yo to

     Lati gboro ayo

     Woli, Oba, ti duro de 

     Nwon wa, nwon ko siri.


4.  Oju wa ti yo to

     To ri ’mole orun

     Oba, Woli, nwon wa titi 

     Nwon si ku, nwon ko ri.


5.  Oluwa, f’ipa han

     Lori gbogbo aiye

     Ki gbogbo orile ede 

     W‘Oba Olorun won.  Amin

English »

Update Hymn