HYMN 232

PB 62 CMS 98 (FE 252) 
“Nje Oluwa ni yi ma se Olorun mi”
- Gen. 28:21



1.  OLORUN Betel, eniti

     O mbo awon Tire 

     Enit’o mu baba wa la 

     Ojo aiye won ja.


2.  A mu eje, at’ebe wa 

     Wa iwaju ‘te Re 

     Olorun awon Baba wa 

     Ma je Olorun wa.


3.  Ninu idamu aiye yi 

     Ma toju ipa wa

     Fun wa ni onje ojo wa 

     At’aso t'o ye wa.


4.  Na ojiji ‘ye Re bo wa 

     Tit’ajo wa o pin

     Ati ni ‘bugbe Baba wa 

     Okan wa o simi.


5.  Iru ibukun bi eyi 

     L’a mbere lowo Re

     Iwo o je Olorun wa, 

     At’ipin wa lailai.  Amin

English »

Update Hymn