HYMN 230

Tune: DCM “Baba Niwaju ite Re”



1.  ODUN miiran tun ti de 

     Ona t’a ko rin ri

     Yoo fun mi ni ikilo 

     B’iranlowo ko si 

     Sugbon Eni t’O to mi 

     Ni odun t’o koja

     Se ‘leri p’Oun yoo duro 

     Ti mi nigba gbogbo.


2.  Odun mii pelu Jesu 

     Emi ko mo ‘foya 

     Yebiye ni ife Re

     B'o ti wu k’iji le 

     Gba t'iji ba tile le 

     No sinmi ninu Re 

     No r’alaafia didun 

     Ni ookan aya Re.


3.  Odun ti n o gbekele E 

     N o tun gbekele I'Eni 

     Ti koja mi kule ri

     Gba ti mo n wo’oju Re 

     O f’ogo at'opa Re 

     Fun mi, fun okun mi 

     Jeejee l’O si n to mi lo 

     L‘ona mi lo s'ile.


4,  Odun miiran lnti sin in 

     Ki n s‘ise fun un nihin 

     Gba l’ojiji tile gun 

     Orun tun n sunmo le

     N ko mo gba ti yoo pe mi 

     Lati f'ise sile

     je ki n le je olooto 

     B’ojo ti n sure lo.


5.  Odun miiran lati fe E 

     Eni ti mo feran

     Odun miiran lati yin in 

     Pelu orin segun 

     Ohun t’ola le mu wa 

     Banuje tab'iya

     lfe Re duro laelae 

     Okan naa ni titi.


6.  Odun mii pelu Jesu

     Oluwa mo dupe 

     F‘oju Re ti ki i kuna 

     L’ona ajo aye

     Joo maa to mi, Oluwa 

     Ko mi ki n se ‘fe Re

     Si mu ete ti Re se

     L‘aye mi l’ojoojo.  Amin

English »

Update Hymn