HYMN 227

P.B C.M.S 101 C.M (FE 247)
‘Olorun si wipe ki imole ki o wa 
l’ofurufu fun ami, fun akako, fun ojo, 
ati fun odun" - Gen. 1:14



1.  OLORUN wa je k'iyin Re 

     Gb'ohun gbogbo wa kan 

     Owo Re yi ojo wa po 

     Odun miran si de.


2.  Ebo wa ngoke sodo Re 

     Baba, Olore wa

     Fun anu ododun ti nsan 

     Lati odo Rewa.


3.  N'nu gbogbo ayida aiye 

     K’anu Re wa sibe 

     B’ore Re si wa si ti po 

     Beni k’iyin wa po.


4.  N'nu gbogbo ayida aiye 

     A nri aniyan Re

     Jowo je k'anu Re ‘kanna 

     Bukun odun titun.


5.  B'ayo ba si wa, k’ayo na 

     Fa wa si odo Re

     B’iya ni awa o korin 

     B’ibukun Re pelu.  Amin

English »

Update Hymn