HYMN 221

H.C 513.8.9 8.8 (FE 240) 
"Ki enyin ki o si ma yo niwaju
Oluwa Olorun nyin" - Lefit. 23:40 
(Tune: A nsoro ile‘bukun ni)



1.  A ki gbogbo nyin ku odun, 

E ku ajoy’odun titun 

E jek’a sope f'Oluwa 

T'o da Emi wa si d'oni.


2.  Opo omode at’agba

T’o ti ngbo ‘mura ajodun yi, 

Opolopo ti koja lo

Won ti file bora b'aso.


3.  Egbe agba alatunse

     E ku atunse egbe na 

     Baba orun yio pelu nyin 

     Yio fi nyin s‘agba kale.


4.  A ki Bale p'e ku odun 

     Ati gbogb’ awon ljoye 

     E ku itoju ilu yi

     Oluwa yio ran yin lowo.


5.  Mase foiya onigbagbo 

     Jesu yio pese l‘odun yi 

     Eni ko bi, iyen a bi 

     Eni bi tire a tunla.


6.  B'ina ku a feru b'oju 

     B'ogede ku a f‘omo ropo 

     O daju pe b'o tile pe 

     Omo wa ni o ropo wa.


7.  Gbogbo alejo, a ki nyin 

     At’ awon olufe owon

     Jesu yio toju ile nyin

     Yio si bukun gbogbo nyin.


8.  A ki nyin pe E ku odun

     Odun titun t’a nse loni 

     K‘Olorun da emi wa si

     Ki gbogbo wa se t‘ amodun.  Amin

English »

Update Hymn