HYMN 218

8s. 8s. 6s. (FE 237)
"Ogo Oluwa yio wa Iailai”
Ohun Orin: “Lehin aiye buburu”



1.  ODUN titun de awa nyo, 

     Tiwa to be, o ju be lo,

     Aw' Egbe Serafu,

     Ko ni gbagbe l’odun to lo, 

     K’ Olorun se ‘yi l’odun 're, 

     E ku ewu odun.


2.  Enyin Om'Egbe Kerubu, 

     K’ e sotiti titi d’opin,

     K‘ emura s’ adura,

     K’ ema woju enikeni,

     E gboran si agba l’ enu, 

     E ye ‘ra odun wo.


3.  Enyin Egbe Aladura,

     K‘ e ranti iran ti e nri, 

     S'ipa iwa rere,

     K’ e mura lati d‘ ohun po, 

     E se ara nyin ni okan,

     E ye ‘ra odun wo.


4.  Awon ti ko gba iran gbo, 

     Nwon dabi ako keferi; 

     Nwon ko mo ‘kan s’okan,

     Bere lowo Jenny Winful,

     Ohun t' ori k’ o to bimo,

     E ye ‘ra odun wo.


5.  K’ a fi keta gbogbo sile, 

     k’ a fe om’ enikeji wa, 

     L’ odun t’ a bo si yi,

     K’ a m soro eni lehin,

     K’ ija gbogbo kuro l’ona, 

     E ye ‘ra odun wo.


6.  Ninu odun t’ a bo si yi,

     Agan a f’ owo s’ osun,

     Olomo a tun bi,

     Enit’ o je ‘gbese y’osan,

     Aje, oso ko ni ri wa,

     E ye ‘ra odun wo.


7.  E wo bi ilu wa ti ri, 

     Ajakal’ arun tun gb'ode, 

     K’Olorun mu kuro,
   
     Nipa awe at‘adura, 

     K’okan gbogbo wa nirepo, 

     E ye ‘ra odun wo.


8.  A ko ri ra, a ko ri ta,

     Ko tun s’ awon alanu mo, 

     Owo ko si l’ode,

     Ibawi Olorun l’eyi,

     K’a ronu k’ a p’iwa wa da, 

     Eye ra odun wo.


9.  Nigbat‘ o ba d’ojo ‘kehin

     Ti omo ko ni mo baba, 

     Oluwa, ranti mi,

     K’a le gbo ohun ‘kele ni, 

     Wipe, ma bo, omo rere,

     K’ a gb’ ade nikehin.  Amin

English »

Update Hymn