HYMN 217

“lfe l'akoja ofin" (FE 236)



1.  JESU loruko to gaju,

     Laiye ati lorun;

     Awon Angeli wole fun, 

     Esu, beru o sa.

Egbe:  Ha! ko s' ariyanjiyan mo,

           Ipe miran ko si,

           O daju wipe Jesu ku, 

           A ni f' emi elese.

2.  Kerubu ati Serafu,

     Nwon yi ‘te Baba ka,

     Nigba gbogbo niwaju Re 

     Nwon nko orin iyin.

Egbe:  Ha! ko s' ariyanjiyan...


3.  Olugbala segun iku,

     ljoba Satan fo;

     Gbogho eda e bu sayo,

     Ka yin Baba logo,

Egbe:  Ha! ko s' ariyanjiyan...


4.  Kerubu ati Serafu,

     E feran ara yin;

     lfe ni awon Angeli,

     Fi nsin Baba loke.

Egbe:  Ha! ko s' ariyanjiyan...


5.  Jesu, Olori Egbe wa,

     Bukun wa laiye wa;

     Jowo pese fun aini wa,

     K’ ebi ale ma pa wa.

Egbe:  Ha! ko s' ariyanjiyan...


6.  Jehovah-Jire Oba wa, 

     Iyin f‘ oruko Re; 

     Ma jeki oso at‘aje,

     Ri wa lojo aiye wa.

Egbe:  Ha! ko s' ariyanjiyan...


7.  Jesu, fo itegun esu,

     Iwo l'Oba Ogo;

     lyin ope ni fun Baba,

     Ni fun Metalokan.

Egbe:  Ha! ko s' ariyanjiyan mo,

           Ipe miran ko si,

           O daju wipe Jesu ku, 

           A ni f' emi elese.  Amin

English »

Update Hymn