HYMN 214

H.C. 111 6s. 8s. (FE 233) 
"O ti ran mi lati kede idasile" - Isa. 61:!



1.  E funpe na kikan, 

     lpe ihinrere,

     K’ odun jake jado, 

     L’ eti gbogbo eda;

Egbe:  Odun idasile ti de; 

            Pada elese e pada.


2.  Fun ‘Pe t' Odagutan; 

     T‘ a ti pa s'etutu, 

     Jeki agbaiye mo, 

     Agbara eje Re.

Egbe:  Odun idasile...


3.  Enyin eru ese, 

     E so ‘ra nyin d' omo, 

     Lowo Kristi Jesu, 

     Egb’Ominira nyin.

Egbe:  Odun idasile...


4.  Olori Alufa, 

     L‘Olugbala ise;

     O fi ‘ra Re rubo 

     Arunkun, aruda. 

Egbe:  Odun idasile...


5.  Okan alare, wa, 

      Simi l‘aya Jesu, 

      Onirobinuje, 

      Tujuka, si ma yo.

Egbe:  Odun idasile ti de; 

            Pada elese e pada.  Amin

English »

Update Hymn