HYMN 212

C.M.S. 91 H.C. 99 P.M. (FE 231)
“Beni ki Iwo ki o ko wa lati ma
ka Iye ojawa, ki awa ki ole fi 
okan wa sipa ogbon" - Ps. 90:12




1.  OJO ati akoko nlo,

     Nwon nsun wa s‘ eti, ‘boji, 

     Awa fere dubule na,

     Ninu iho ‘busun wa.


2.  Jesu, ’Wo Olurapada,

     Ji okan t’ oku s’ ese;

     Ji gbogbo okan ti ntogbe, 

     Lati yan ipa iye.


3.  Bi akoko ti nsunmole, 

     Jek’ a ro ‘ bi ti anlo; 

     Bi lati r’ayo ailopin, 

     Tabi egbe ailopin.


4.  Aiye wa nlo!

     Iku de tan,

     Jesu, so wa,

     Tit' O fi de,

     K’a a ba O gbe,

     K’ aba O ku,

     K‘ a ba O joba titi lailai.


5.  Aiye wa nkoja b’ ojiji, 

     O si nfo lo bi ‘kuku; 

     Fun gbogbo odun t’ o 

     K oja,

     Dariji wa, mu wa gbon.


6.  Ko wa lati ka ojo wa,

     Lari ba ese wa ja,

     K'a ma sure, k’ a ma togbe, 

     Tit'a o fi ri ‘sinmi.


7.  Gbogbo wa fere duro na, 

     Niwaju ite ‘ dajo;

     Jesu, ‘ Wo t’o segun iku, 

     Fi wa s' apa otun Re.


8.  Aiye wa nlo!

     Iku de tan, Olugbala!

     Jo pa wa mo, K’ a ba O gbe, 

     K’a ba O ku,

     K’ a ba O joba titi lailai.  Amin

English »

Update Hymn