HYMN 21

C.M.S 25, H.C 218 t (FE 38) H.C 96D, 
7S 6s
"Ojo Oluwa" - Ifi. 1:10s


1.  OJO isimi at’ayo

     Ojo inu didun; 

     Ogun fun ibanuje 

     Ojo dida julo

     Ti awon eni giga 

     Niwaju ite Re 

     Nko mimo, mimo, mimo 

     S’eni Metalokan.


2.  L’ojo yi ni ‘mole la, 

     Nigba dida aiye

     Ati fun igbala wa 

     Kristi jinde loni, 

     L‘ojo oni l’Oluwa 

     Ran Emi torun wa; 

     Ojo ologo julo

     T’o ni mole pipe.


3.  Orisun ‘tura ni O, 

     L’aiye aginju yi,

     L’ori Re, bi ni Pisga 

     L’a nwo ‘le ileri 

     Ojo ironu didun 

     Ojo ife mimo

     Ojo ajinde, lati 

     Aiye si nkan orun.


4.  L’oni s’ilu t’are mu, 

     Ni manna t’orun bo, 

     Si ipejopo mimo 

     N’ipe fadaka ndun, 

     Nibiti ihin-rere, 

     Ntan imole mimo 

     Omi iye nsan jeje

     Ti ntu okan lara.


5.  K’a r’ore‐ofe titun 

     L’ojo ‘simi wa yi

     Ka si de simi t’o ku 

     F’awon alabukun 

     Nibe ka gbohun soke 

     Si Baba at’Omo

     Ati si Emi Mimo

     N’iyin Metalokan.  Amin

English »

Update Hymn