HYMN 207

t. C.M.S. 86 t.H.C. 553, (FE 227)
"Awa omo yo, inu wa yio si ma dun"
- Ps.118:24



1.  ONIGBAGBO, e bu s’ ayo, 

     Ojo nla l’eyi fun wa;

     E gbo bi awon Angeli,

     Ti nfi Ogo fun Olorun, 

     Alafia, Alafia,

     Ni fun gbogbo enia.


2.  Ki gbogbo aiye ho f‘ ayo; 

     K‘ a f'ogo fun Olorun; 

     Omo bibi Re l’ O fun wa; 

     T‘ a bi ninu Wundia, 

     En’lyanu, En‘ Iyanu,

     Ni Omo t’a bi loni.


3.  Ninu gbogbo rudurudu 

     Ohun ibi t’ okun aiye, 

     Ninu idamu nla ese, 

     L’ Om’ Olorun wa gba wa; 

     Olugbimo, Olugbimo, 

     Alade alafia.


4.  Olorun Olodumare;

     L’ a bi. bi omo titun; 

     Baba! Eni aiyeraiye; 

     L’odi alakoso wa:

     E bu s‘ayo, E bu s’ayo 

     Omo Dafidi joba.


5.  O wa gba wa lowo ese, 

     O wad‘onigbowo wa, 

     Lati fo itegun esu,

     A se ni Oga ogo:

     E ku ayo, e ku ayo,

     A gba wa lowo iku.  Amin

English »

Update Hymn