HYMN 202

C.M.S.467 H.C.474 8s. 7s. (FE 221)
"Omo na ni Jesu." - Luku 2:43



1.  NIGBA kan ni Betlehemu, 

     lle kekere kan wa;

     Nib‘iya kan te ‘mo re si, 

     Lori ibuje eran;

     Maria n'iya omo na, 

     Jesu Kristi l‘omo na.


2.  O t‘orun wa sode aiye, 

     On li Olorun Oluwa, 

     O f' ile eran se ile, 

     ‘Buje eran fun ‘busun; 

     L’odo awon otosi,

     Ni Jesu gbe li aiye.


3.  Ni gbogbo igba ewe Re, 

     O gboran o si mb’ola;

     O feran o si nteriba, 

     Fun iya ti ntoju Re;

     O ye ki gbogb’ omode, 

     Ko se olugboran be.


4.  'Tori On je awose wa, 

     A ma dagba bi awa;

    O kere kole dankan se, 

    A ma sokun bi awa;

    O si le ba wa daro, 

    O le ba wa yo pelu.


5.  A o f‘oju wa ri nikehin 

     Ni agbara ife Re; 

     Nitori Omo rere yi,

     Ni Oluwa wa l’orun: 

     O nto awa omo Re; 

     S’ona ibiti On lo.


6.  Ki se ni ibuje eran,

     Nibiti malu njeun; 

     L‘awa ori l sugbon l’orun, 

     L'owo otun Olorun, 

     'Gba won ‘mo Re B‘irawo, 

     Ba ntan nin’aso ala.  Amin

English »

Update Hymn