HYMN 201

C.M.S.87  H.C.86  P.M (FE 220)
"E je ki a lo si Betlehem tara, ki a le
ri ohun ti o se" - Luku 2:15



1.  WA, enyin oloto,

     L'a yo at'isegun,

     Wa k'a lo, wa ka lo si Betlehem,

     Wa ka lo wo O!

     Oba awon Angel.

Egbe:  E wa ka lo juba Re,

            E wa ka lo juba Re,

            E wa k' a lo juba

            Kristi Oluwa.


2.  Olodumare ni,

     Imole Ododo,

     Ko si korira inu Wundia;

     Olorun papa ni,

     Ti a bi, t'a ko da.

Egbe:  E wa ka lo juba Re...


3.  Angeli, e korin,

     Korin itoye Re;

     Ki gbogbo eda orun si gberin: 

     Ogo f’ Olorun 

     L’oke orun l'ohun:

Egbe:  E wa ka lo juba Re...


4.  Nitoto, a wole,

     F'Oba t’ a bi loni:

     Jesu lwo li awa nfi ogo fun, 

     ‘Wo Omo baba,

     T’o gbe ara wa wo!

Egbe:  E wa ka lo juba Re,

            E wa ka lo juba Re,

            E wa k' a lo juba

            Kristi Oluwa.  Amin

English »

Update Hymn