HYMN 196

8.7.8.7.8.8.7 & Ref
"O si mu mi goke pelu, lati inu iho
iparun jade wa" - Od. 40:2




1.  OKAN wa kun f'ayo loni 

     A ti r‘ona wura na 

    Imole re nta l‘ona wa 

    A ti r’ona wura na

    O ti pe t’ayun Re nyun wa

    Larin ayidayid’ aye

    Die lo ku fun wa k'o bo 

    K'a to r‘ona wura na. 

Egbe:  Nje korin, korin ayo 

           F'okan ayo korin soke 

           Imole de, a de ‘ile wa

           Ati r'ona wura na.


2.  A pe wa kuro l'aye yi

     A ti r‘ona wura na

    Ore wa gbogbo wa nibe 

    A ti r'ona wura na 

    Awa jeri pe didun na 

   K'a ma tase ijoba orun 

   Pelu Jesu a nlo ‘le wa

   A ti r‘ona wura na.

Egbe:  Nje korin, korin ayo...


3.  Kiun ni ‘danwo wa t‘o koja 

     A ti t'ona wura na

     Ayo ile mu k’a gbagbe

    A ti r’ona wura na

    ‘Ji kuku ko ni pe kuro 

    lfayabale yoo si de

    A ta ‘gbokun, oko si gun le 

    A ti r’ona wura na.

Egbe:  Nje korin, korin ayo...


4.  Pel'okan ‘es‘Olorun wa 

     A ti r’ona wura na 

     Lekan ri ti a ti sonu

     A ti r‘ona wura na

     A fe d’odo Olugbala 

    Jesu yoo f'ayo gba wa 

    O je nipa or’ofe nikan 

    A ti r‘ona wura na.

Egbe:  Nje korin, korin ayo...



5.  A dupe low’Olorun wa

    Ti p’a r’ona wura na

    Iyin, ogo ope, ola

    Fun Baba ati Omo

    Ati pelu Emi Mimo

    Metalokan ayeraye

    Titi aye lao ma yin
 
    Pe a r'ona wura na.

Egbe:  Ope ni fun O Elshadai 

           Jehofa Rofai ni k’ayin 

           Aleluya orin iyin

           Fun Metalokan soso.  Amin

English »

Update Hymn