HYMN 192

C.M. 56 t.H.C 154 C.M. (FE 210) 
"E pese okan nyin sile"
- 1 Sam. 7:3



1.  JESU t'o ga julo lorun 

     lpa Re l'od’aiye

     ‘Wo f‘ogo nlanla Re sile 

     Lati gba aiye la.


2.  O w' aiye airo irele 

     Ni ara osi mi wa 

     Nitori k‘okan t‘o sile 

     Be t’ipase Re la.


3.  Wiwa Re ya Angeli l‘enu 

     Ife t‘o tobi ni

     Enia l'anfani iye

     Angeli se, ko ni.


4.  Nje araiye yo, sa nyin de, 

     E ho iho ayo

     lgbala mbo fun elese 

     Jesu Olorun ni.


5.  Oluwa, jo ki bibo Re 

     Nigba erinkeji

     Je ohun ti a nduro de, 

     K’ o le ba wa Layo.  Amin

English »

Update Hymn