HYMN 189

C.M.S 61 O.P.M (FE 207)
"Alabukun fun ni enyin ti nforugbin
niha omi gbogbo" - Isa 32:2



1.  ARA mi fun ‘rugbin rere 

     Nigba ifurugbin wa

     Ma sise l'Oruko Jesu 

     Tit’ On o tun pada wa. 

Egbe:  Nigbane ni a o f'ayo ka a

           Olukore y'o ko won si aba

           Nigbane ni a o f'ayo ka a

           Olukore y'o ko won si aba.


2.  Olugbala pase wipe, 

     Sise nigbat‘o j‘osan 

     Oru mbowa, mura giri 

     Oloko fere de na.

Egbe:  Nigbane ni a...


3.  T’agba tewe jumo ke, pe, 

     'Wo l'Oluranlowo wa

     Mu ni funrugbin igbagbo

     K'a s’ ero itewogba.

Egbe:  Nigbane ni a...


4.  Lala ise fere d‘opin
  
     Owo wa fe ba ere

     B'o de ninu olanla Re,

     Yo so fun wa pe, “Siwo” 

Egbe:  Nigbane ni a o f'ayo ka a

           Olukore y'o ko won si aba

           Nigbane ni a o f'ayo ka a

           Olukore y'o ko won si aba.  Amin

English »

Update Hymn