HYMN 186

C.M.S. 55 H.C 62 62 2nd Ed
tabi t. H. C. 173 1.M (FE 204)
“O mbo lati se idajo aiye“ - Ps. 96:13



1.  OLUWA mbo; aiye o mi 

     Oke y'o si di n’ipo won 

     At’irawo oju orun

     Y'o mu imole won kuro.


2.  Oluwa mbo, bakanna ko 

     Bi oti wa n'irele ri 

     Odo-agutan ti a pa 

     Eni-iya ti o si ku.


3.  Oluwa mbo. li eru nla 

     L‘owo ina pelu Ija 

     L'or'iye apa Kerubu 

     Mbo, Onidajo araiye.


4.  Eyi ha li eniti nrin

     Bi ero l’opolopo aiye? 

     'Ti a se 'nunibini si? 

     A! Eniti a pa l’eyi?


5.  Ika: b'e wo 'nu apata 

     B'e wo n'nu iho, lasan ni

     Sugbon igbagbo t'osegun

     Y'o korin pe, Oluwa de.  Amin

English »

Update Hymn