HYMN 180

C.M.S. 71 H.C. 74 P.M (FE 198)
"Igba awon oku de ti a o da won 
l’eja” - Ifi. 11:18



1.  OLORUN, kini mo ri yi! 

     Opin de f’ohun gbogbo 

     Onidajo araiye yo,

     O gunwa n‘ite ‘dajo

     Ipe dun iboji si tu 

     Gbogbo awon oku sile 

     Mura, lo ko, okan mi.


2.  Oku n’nu Krist’ y’o ko jinde 

     Nigba ‘pe ‘kehin ba dun 

     Nwon o lo ko, l’awosanma, 

     Nwon o fi ayo yi ka

     Ko s’ eru ti y’o b‘okan won 

     Oju Re da imole bo

     Awon ti o mura de.


3.  Sugbon elese t’on t’eru!

     Ni gbigbona ‘binu Re

     Nwon o dide, nwon o si ri, 

     Pe, o se, nwon ko ba mo

     Ojo Ore-Ofe koja 
   
     Nwon ngbon niwaju ‘te ‘dajo’ 

     Awon ti ko mura de.


4.  Olorun, kini mo ri yi 
  
     Opin de f'ohun gbobgo!

     Onidajo araiye yo 

     O gunwa n‘ile ‘dajo 

     L‘ese agbelebu mo nwo 

     Gbat’ ohun gbogbo y'o koja

     Bayi ni ngo mura de.  Amin

English »

Update Hymn