HYMN 18

C.M.S 16, H.C 21, L.M (FE 35)
“Emi o dubule Ii alafia" - Ps. 4:8


1.  IWO imole okan mi,

     Li odo Re oru ko si

     Ki kuku aiye ma bo o,
    
     Kuro I'oju iranse Re.


2.  Nigba t'orun ale didun 

     Ba npa ipenpeju mi de 

     K‘ero mi je lati simi 

     Lai l’aiya Olugbala mi.


3.  Ba mi gbe l'oro tit'ale 

     Laisi Re emi ko le wa, 

     Ba mi gbe gbat’ile ba nsu 

     Laisi Re, emi ko le ku


4.  Bi otosi omo Re kan, 

     Ba tapa s'oro Re loni 

     Oluwa, sise oro Re 

     Ma jek'o sun ninu ese


5.  Bukun fun awon alaisan 

     Pese fun awon talaka

     K‘orun alawe l'ale yi 

     Dabi orun omo titun.


6.  Sure fun wa nighat’ aji, 

     K'a to m’ohun aiye yi se,

     Titi awa o de bite

     T'a o si de ijoba Re.  Amin

English »

Update Hymn